8 Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo.
9 Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:“Ó tí fọ́nká; ó ti fifún àwọn talákà;Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”
10 Ǹjẹ́ ẹni tí ń fí irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i.
11 Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.
12 Nítorí iṣẹ́-ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn-mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run.
13 Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́-ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìn rere Kírísítì àti nípa ìlawọ́ ìdánwò yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn.
14 Nígbà tí àwọn tìkárawọn pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ fún un yín ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín.