35 Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.
36 Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní suuru, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.
37 Nítorí ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,“Ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara.
38 Ṣùgbọ́n olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́:Ṣùgbọ́n bí o ba fà sẹ́yìn,ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”
39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.