1 Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a sẹ̀sẹ̀ gba Kírísítì sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbà sókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ síhà ti Ọlọ́run,
2 ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitísìmù, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun.
3 Èyí ní àwá yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.
4 Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábàápín Ẹ̀mí Mímọ́,
5 tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀,
6 láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélèbú sí ara wọn lọ́tún, wọ́n sì dójú tì í ní gbangba.
7 Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hú ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run.
8 Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná
9 Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwá ní ìgbàgbọ́ ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní ti yín, àti ohun tí ó faramọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀.
10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yín fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe.
11 Àwá sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsinmi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin:
12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.
13 Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Ábúráhámù, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé,
14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.”
15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ̀yìn ìgbà tí Ábúráhámù fi súúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.
16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀ṣẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀.
17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidgidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrin wọn.
18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú sinsin:
19 Èyí tí àwa ní bi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ̀yìn aṣọ ìkélé;
20 Níbi tí Jésù, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ Olórí àlùfáà títí láé nípasẹ̀ Melekisédékì.