Àwọn Hébérù 11 BMY

Nípa Ìgbàgbọ́

1 Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń réti, ìjeri ohun tí a kò rí.

2 Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà (atijọ́) ní ẹ̀rí rere.

3 Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.

4 Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábélì rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Káínì lọ, nípa èyí tí a jẹ̀rí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́ri ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.

5 Nípa ìgbàgbọ́ni a sì Énókù nípò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sí rí i, nítorí ti Ọlọ́run ṣi i nípò padà: nítorí ṣaáju ìsìpo padà rẹ̀, a jẹ́ri yìí si i pé o wu Ọlọ́run.

6 Ṣùgbọ́n làísí ìgbàgbọ́ kò ṣeéṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè sàì gbàgbọ́ pé o ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.

7 Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóàh, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tíì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ̀bí, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.

8 Nípa ìgbàgbọ́ ní Ábúráhámù, nígbà tí a ti pé e láti jáde lọ sí ibi tí òun yóò gbà fún ilẹ̀ ìní, ó gbọ́, ó sì jáde lọ, láì mọ ibi tí òun ń rè.

9 Nípa ìgbàgbọ́ ní o ṣe àtìpó ní ilẹ̀ ìlérí, bí ẹni pé ni ilẹ̀ àjèjì, o ń gbé inú àgọ́, pẹ̀lú Ísáákì àti Jákọ́bù, àwọn ajogún ìlérí kan náà pẹ̀lú rẹ̀:

10 Nítorí tí ó ń rétí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀; ọ èyí tí Ọlọ́run tẹ̀dó tí o si kọ́.

11 Nípa ìgbàgbọ́ ni Sárà tìkararẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọja ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérì sí olootọ́.

12 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọpọ̀, àti bí ìyanrìn etí òkun láìníyè.

13 Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o kú ní ìgbàgbọ́, láì rí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, ti wọn si gbá wọn mú, tí wọn sì jẹ̀wọ́ pé àlejò àti àtìpó ni àwọn lórí ilẹ́ ayé.

14 Nítorí pé àwọn tí o ń ṣọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn.

15 Àti ní tòótọ́, ìbáṣe pé wọn fi ìlú ti wọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí àyè padà.

16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n ń fẹ́ ìlú kan tí o dá jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí yìí ni ti ọ̀run: nítorí náà ojú wọn kò ti Ọlọ́run, pé kí a máa pé òun ni Ọlọ́run wọn; nítorí tí o ti pèsè ìlú kan sílẹ̀ fún wọn.

17 Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dan an wò, fi Ísáákì rúbọ: àní òun ẹni tí ó rí ìlérí gba múra tan láti fi ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo rúbọ,

18 Nípa ẹni tí wí pé, “Nínú Ísáákì ni a o ti pé irú ọmọ rẹ̀:”

19 Ó sì rò ó si pé Ọlọ́run tilẹ̀ lè gbé e dìdè kúrò nínú òkú, bẹ́ẹ̀ ni, bí a bá sọ ọ lọ́nà àpẹẹrẹ, ó gbà á padà.

20 Nípa ìgbàgbọ́ ní Ísáákì súre fún Jákọ́bù àti Ísọ̀ níti ohun tí ń bọ̀.

21 Nípa ìgbàgbọ́ ni Jákọ́bù, nígbà ti o ń ku lọ, ó súrre fún àwọn ọmọ Jósẹ́fù ni ìkọ̀ọ̀kan; ó sì sìn ní ìtẹriba lé orí ọ̀pá rẹ̀.

22 Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì; ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀.

23 Nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn òbí Móṣè pa a mọ́ fún oṣù mẹ́ta nígbà tí a bí i, nítorí ti wọn rí i ní arẹwà ọmọ; wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

24 Nípa ìgbàgbọ́ ni Móṣè, nígbà tí o dàgbà, ó kọ̀ ki a máa pé òun ni ọmọ ọmọ-bìnrin Fáráò;

25 Ó kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgba díẹ̀.

26 Ó ka ẹ̀gàn Kírísítì si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúrà Éjípítì lọ: Nítorí tí ó ń wo èrè náà.

27 Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Éjípítì sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí.

28 Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrekọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má báa fí ọwọ́ kan wọn.

29 Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun púpa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: Ti àwọn ara Éjípítì dánwo, ti wọn sì ri.

30 Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jẹ́ríkò wo lulẹ̀, lẹ̀yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ijọ́ méje.

31 Nípa ìgbàgbọ́ ni Ráhábù panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́ràn nígbà tí o tẹ́wọ́gba àwọn àmì ní àlàáfíà.

32 Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mú láti sọ ti Gídíónì, àti Bárákì, àti Sámsónì, àti Jẹftà; àti Dáfídì, àti Sámúẹ́lì, àti ti àwọn wòlíì:

33 Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ti wọn sẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ òdodo, ti wọn gba ìlérí, ti wọn dí àwọn kìnnìún lẹ̀nu,

34 Tí wọn pa agbára iná, ti wọn bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, ti wọn dí akọni ni ìjà, wọn lé ogun àwọn àjèjì sá.

35 Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà;

36 Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú:

37 A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọn rìn kákiri nínú àwọ àgùntàn àti nínú àwọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olupọ́njú, ẹni tí a ń da lóró;

38 Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọn ń kiri nínú àsálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.

39 Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́ri rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà:

40 Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí o dárajù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13