1 Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà,
2 ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kírísítì, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀:
3 Ọmọ tí í ṣe ìtànsán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkálárarẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ọlá-ńlá ní òkè.
4 Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju ańgẹ́lì lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ ti wọn.
5 Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn ańgẹ́lì tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé:“Ìwọ ni ọmọ mi;lónì- ni mo bí ọ”?Àti pẹ̀lú pé;“Èmi yóò jẹ́ baba fún-un,Òun yóò sì jé ọmọ mi”?
6 Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé,“Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”
7 Àti nípa ti àwọn ańgẹ́lì, ó wí pé;“Ẹni tí ó dá àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ẹ̀mi,àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ ìná.”
8 Ṣùgbọ́n ó sọ nípa tí Ọmọ rẹ̀ pé,“Ọlọ́run, ìjọba rẹ yóò wà láti ìran dé ìran,àti pé òdodo ni ọ̀pá tí ìwọ fi ń páṣẹ ìjọba rẹ.
9 Ìwọ fẹ́ òdodo,bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kórìíra iṣẹ́ búburú;nítorí èyí ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ ṣe fi òróró ayọ̀ yàn ọtí ó gbé ọ ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ lọ.”
10 Ó tún sọ pé,“Ní àtètèkọ́ṣe, ìwọ Olúwa, ìwọ fi ìdí ayé sọlẹ̀,àwọn ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ.
11 Wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà síbẹ̀gbogbo wọn ni yóò gbó di àkísà bí ẹ̀wù.
12 Ní kíká ni ìwọ yóò ká wọn bí aṣọ,bí ìpàrọ̀ aṣọ ni a ó sì pàárọ̀ wọn.Ṣùgbọ́n ìwọ fúnrarẹ kì yóò yípadààti pé ọdún rẹ kì yóò ní òpin.”
13 Èwo nínú àwọn ańgẹ́lì ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé,“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mitítí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”?
14 Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jísẹ́ ni àwọn ańgẹ́lì í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa sisẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?