1 Bẹ́ẹ̀ ni májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní ìlànà fún ìsìn àti ibi mímọ́ ti ayé yìí.
2 A gbé agọ́ kan dìde. Nínú yàrá rẹ̀ àkọ́kọ́ ni a ti rí ọ̀pá fìtílà, tábìlì, àti àkàrà ìfihàn. Èyí tí a ń pè ní ibi mímọ́.
3 Àti lẹ́yìn aṣọ ìkelé kejì, òun ni àgọ́ tí à ń pè ní ibi mímọ́ jùlọ;
4 Tí ó ní àwo tùràrí wúrà, àti àpótí májẹ̀mú tí a fi wúrà bò yíká, nínú èyí tí ìkòkò wúrà tí ó ní mánà gbé wà, àti ọ̀pá Árónì tí o rúdí, àti àwọn wàláà májẹ̀mú;
5 Àti lórí rẹ̀ ni àwọn kérúbù ògo ti i ṣíji bo ìtẹ́ àánú; èyí tí a kò lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ nísinsin yìí lọ́kọ̀ọ̀kan;
6 Ǹjẹ́ nígbà tí a ti ṣe ètò nǹkan wọ̀nyí báyìí, àwọn àlùfáà a máa lọ nígbàkúgbà sínú àgọ́ èkínní, wọn a máa ṣe iṣẹ́ ìsìn.
7 Ṣùgbọ́n sínú èkejì ni olórí àlùfáà nìkan máa ń lọ lẹ́kan ṣoṣo lọ́dún, fún ara rẹ̀, àti fún ìsìnà àwọn ènìyàn.
8 Ẹ̀mí mímọ́ ń tọ́ka èyí pé a kò ì tí ì ṣí ọ̀nà ibi mímọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ èkíní bá sì dúró,
9 (Èyí tí i ṣe àpẹẹrẹ fún ìgbà ìsinsin yìí). Gẹ́gẹ́ bí ètò yìí, a ń mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá, tí kò lè mú ẹ̀rí ọkàn olùsìn di pípé,
10 Èyí sì wà nínú ohun jíjẹ àti ohun mímu àti onírúurú ìwẹ̀, tí ì iṣe ìlànà ti ara nìkan tí a fi lélẹ̀ títí fi di ìgbà àtúnṣe.
11 Ṣùgbọ́n nígbà tí Kírísítì dé bí Olórí àlùfáà àwọn ohun rere tí ń bọ̀, nípaṣẹ̀ àgọ́ tí o tóbi ti ó sì pé ju ti ìṣáájú, (èyí tí a kò fi ọwọ́ dá, èyí yìí ni, tí kì í ṣe ti ẹ̀dá yìí),
12 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa.
13 Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eerú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọni-di-mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:
14 Mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kírísítì, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?
15 Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ilèrí ogún àìnípẹ̀kun gbà.
16 Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;
17 Nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ̀yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú: Nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láàyè.
18 Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú páàpáà sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.
19 Nítorí nígbà tí Mósè ti sọ gbogbo àṣẹ nípa ti òfin fún gbogbo àwọn ènìyàn, ó mú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù àti ti ewúrẹ́, pẹ̀lú omi, àti òwú òdòdó, àti ewé hísọ́pù ó sì fi wọ́n àti ìwé páàpáà àti gbogbo ènìyàn.
20 Wí pé, “Èyí ní ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run paláṣẹ fún yín.”
21 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ó sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n àgọ́, àti gbogbo ohun èlò ìsìn.
22 Ó sì fẹ́rẹ̀ jẹ́ ohun gbogbo ni a fi ẹ̀jẹ̀ wẹ̀nù gẹ́gẹ́ bí òfin; àti pé láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀ kò sí ìdáríjì.
23 Nítorí náà a kò lè ṣàì fi ìwọ̀nyí we àwọn àpẹẹrẹ ohun tí ń bẹ lọ́run mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ju ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run páàpáà mọ́; ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi ẹbọ tí ó sàn ji ìwọ̀nyí lọ wẹ àwọn ohun ọ̀run páàpáà mọ́.
24 Nítorí Kírísítì kò wọ ibi mímọ́ tí a fi ọwọ́ ṣe lọ tí i ṣe àpẹẹrẹ ti òtítọ́; ṣùgbọ́n ó lọ sí ọ̀run páàpáà, nísinsin yìí láti farahàn ní iwájú Ọlọ́run fún wa:
25 Kì í si i ṣe pé kí ó lè máa fi ara rẹ̀ rúbọ nígbàkúgbà, bí olórí àlùfáà tí máa ń wọ inú ibi mímọ́ lọ lọ́dọọdún ti oun pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ti kì í ṣe tirẹ̀;
26 Bí bẹ́ẹ̀ bá ni oun ìbá tí máa jìyà nígbàkúgbà láti ìpìlẹ̀ ayé: Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ni ó fi ara hàn lẹ́ẹ́kanṣoṣo lópìn ayé láti mi ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nípa ẹbọ ara rẹ̀.
27 Níwọ̀n bí a sì ti fi lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti kú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo, ṣùgbọ́n lẹ̀yìn èyí ìdájọ́:
28 Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú lẹ̀yìn tí a ti fi rúbọ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀, yóò farahàn ní ìgbà kéjì láìsí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí n wo ọ̀nà rẹ̀ fún ìgbàlà.