8 Jésù Kírísítì ọ̀kan náà ni lánà, àti lóní, àti títí láé.
9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè.
10 Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.
11 Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ̀yìn ibùdó.
12 Nítorí náà Jésù pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ̀yìn ìbodè.
13 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ̀yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀.
14 Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níyin, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.