15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọjọ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.
16 Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn ańgẹ́lì ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Ábúráhámù ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún.
17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ Olórí Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.
18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkararẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.