1 Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábàápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti Àpósítélì àti Olórí Àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jésù;
2 Ẹni tí o ṣe olóòótọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mósè pẹ̀lú tí ṣe olóòótọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo ilé Ọlọ́run.
3 Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mósè lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ.
4 Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.
5 Mósè nítòótọ́ sì ṣe olóòótọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ̀n ní ìgbà ìkẹyìn.