10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn sìnà ní ọkàn wọn;wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Bí mo tí búra ní ìbínú mi,‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”
12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.
13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.
14 Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;
15 Nígbà tí a ń wí pé:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má se ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìmúnibínú.”
16 Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Éjíbítì ní abẹ́ àkóso Mósè?