13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjù ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnìkẹni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.
14 Nítorí àwá di alábàápín pẹ̀lú Kírísítì, bí àwá bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin;
15 Nígbà tí a ń wí pé:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má se ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìmúnibínú.”
16 Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Éjíbítì ní abẹ́ àkóso Mósè?
17 Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní ihà?
18 Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?
19 Àwá sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.