4 Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run.
5 Mósè nítòótọ́ sì ṣe olóòótọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ̀n ní ìgbà ìkẹyìn.
6 Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.
7 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mi Mímọ́ tí wí:“Lònì-ín bí ẹ̀yín bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 Ẹ má ṣe sé ọ̀kan yin le,bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní ihà:
9 Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn sìnà ní ọkàn wọn;wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’