1 Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un.
2 Ẹni tí Ábúráhámù sì pin ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún; lọ́nà èkíniní nínú ìtumọ̀ rẹ̀, “Ọba òdodo,” àti lẹ̀yìn náà pẹ̀lú, “ọba Sálẹ́mù,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.”
3 Láínì baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.
4 Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Ábúráhámù baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún.