11 Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì?
12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin.
13 Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kòì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ.
14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Júdà ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mósè kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.
15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà míràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melikísédékì.
16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin.
17 Nítorí a jẹri pé:“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipaṣẹ̀ ti Melikísédékì.”