14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Júdà ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mósè kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.
15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà míràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melikísédékì.
16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin.
17 Nítorí a jẹri pé:“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipaṣẹ̀ ti Melikísédékì.”
18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìléera àti àìlérè rẹ̀.
19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
20 Níwọ̀n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni.