6 Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí,
7 láìsí ìjìyàn rárá ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè ni.
8 Àti níyin, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè nì.
9 Àti bí a ti lè wí, Léfì pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù.
10 Nítorí o sáa sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melikísédékì pàdé rẹ̀.
11 Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì?
12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin.