12 Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ọmọ màlúù, ṣùgbọ́n nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀, o wọ ibi mímọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, lẹ́yìn tí ó ti rí ìdáǹdè àìnípẹ̀kun gbà fún wa.
13 Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ àti ti akọ màlúù àti eerú ẹgbọrọ abo màlúù tí a fi wọ́n àwọn tí a ti sọ di aláìmọ́ ba ń sọni-di-mímọ́ fún ìwẹ̀nùmọ́ ara:
14 Mélòómélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kírísítì, ẹni, nípa Ẹ̀mí ayérayé, tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ sí Ọlọ́run láìní àbàwọ́n, yóò wẹ èérí ọkàn yín nù kúrò nínú òkú iṣẹ́ láti sin Ọlọ́run alààyè?
15 Àti nítorí èyí ni ó ṣe jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun pé bí ikú ti ń bẹ fún ìdáǹdè àwọn ìrékọjá ti o tí wà lábẹ́ májẹ̀mú ìṣáájú, kí àwọn tí a ti pè lè rí ilèrí ogún àìnípẹ̀kun gbà.
16 Nítorí níbi tí ìwé ogún bá gbé wà, ikú ẹni tí o ṣe é kò lè ṣe àìsí pẹ̀lú;
17 Nítorí ìwé ogún ní agbára lẹ̀yìn ìgbà tí ènìyàn bá kú: Nítorí kò ní agbára rárá nígbà tí ẹni tí o ṣè e bá ń bẹ láàyè.
18 Nítorí náà ni a kò ṣe ya májẹ̀mú ìṣáájú páàpáà sí mímọ́ láìsí ẹ̀jẹ̀.