18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, àwọn tí ó sì di àjèjì sí ìwà-bí-Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí lílè ọkàn wọn.
19 Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọ́ra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.
20 Ṣùgbọ́n a kò fi Kírísítì kọ́ yín bẹ́ẹ̀.
21 Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí otítọ́ ti ń bẹ nínú Jésù.
22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn;
23 Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín;
24 Kí ẹ sì gbé ọkùnrin titun wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.