2 Pẹ̀lu ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín.
3 Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.
4 Ara kan ni ń bẹ, ati Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín.
5 Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan, ìtẹ̀bọmi kan.
6 Ọlọ́run kan ati Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó se olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú gbogbo.
7 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kírísítì.
8 Nitorí náà a wí pé:“Nígbà tí ó gókè lọ sí ibi gíga,ó di ìgbékùn ni ìgbékùn,ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”