1 Ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí púpọ̀ nínú yín jẹ́ olùkọ́, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé àwa ni yóò jẹ̀bi jù.
2 Nitorí nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣe àṣìse. Bí ẹni kan kò bá sì sì ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé, òun ni ó sì le kó gbogbo ara ní ìjánu.
3 Bí a bá sì fi ìjánu bọ ẹṣin lẹ́nu, kí wọn kí ó le gbọ́ tiwa, gbogbo ara wọn ni àwa sì ń tì kiri pẹ̀lú.
4 Kíyèsí i, àwọn ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú, bí wọ́n ti tóbi tó nì, tí a sì ń ti ọwọ́ ẹ̀fúùfù líle gbá kiri, ìtọ́kọ̀ kékeré ni a fi ń darí wọn kiri, síbikíbi tí ó bá wu ẹni tí ó ń tọ́ ọkọ̀.
5 Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ahọ́n jẹ́ ẹ̀yà kéreré, ó sì ń fọhùn ohùn ńlá. Wo igi ńlá tí iná kékeré ń sun jóna!
6 Iná sì ni ahọ́n, ayé ẹ̀ṣẹ̀ sì ni: ní àárin àwọn ẹ̀yà-ara wa, ní ahọ́n ti ń bá gbogbo ara jẹ́, tí yóò sì ti iná bọ ipa ayé wa; ọ̀run àpáàdì a sì tiná bọ òun náà.