6 Ó ní: “Àwọn ará Gasa ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí odidi orílẹ̀-èdè kan ni wọ́n kó lẹ́rú, tí wọ́n lọ tà fún àwọn ará Edomu.
7 N óo sọ iná sí ìlú Gasa, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.
8 N óo pa gbogbo àwọn ará Aṣidodu run ati ọba Aṣikeloni; n óo jẹ ìlú Ekironi níyà, àwọn ará Filistia yòókù yóo sì ṣègbé.” OLUWA Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀.
9 Ó ní: “Àwọn ará Tire ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n kó odidi orílẹ̀-èdè kan lẹ́rú lọ tà fún àwọn ará Edomu. Wọn kò sì ranti majẹmu tí wọ́n bá àwọn arakunrin wọn dá.
10 Nítorí náà n óo sọ iná sí orí odi ìlú Tire, yóo sì jó ibi ààbò rẹ̀ ní àjórun.”
11 OLUWA ní: “Àwọn ará Edomu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n dojú idà kọ arakunrin wọn, láìṣàánú wọn, wọ́n bínú kọjá ààlà, títí lae sì ni ìrúnú wọn.
12 Nítorí náà, n óo rán iná sí ìlú Temani, yóo sì jó ibi ààbò Bosira ní àjórun.”