Amosi 9 BM

Ìdájọ́ OLUWA

1 Mo rí OLUWA, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ó pàṣẹ pé, “Lu àwọn òpó tẹmpili títí tí gbogbo àtẹ́rígbà rẹ̀ yóo fi mì tìtì, tí yóo sì wó lé gbogbo àwọn eniyan lórí. N óo jẹ́ kí ogun pa àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù lára wọn, Kò ní sí ẹyọ ẹnìkan ninu wọn tí yóo lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹnìkan tí yóo sá àsálà.

2 Bí wọ́n tilẹ̀ gbẹ́ ilẹ̀ tí ó jìn bí isà òkú, ọwọ́ mi yóo tẹ̀ wọ́n níbẹ̀; bí wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run, n óo wọ́ wọn lulẹ̀ láti ibẹ̀.

3 Bí wọ́n bá sápamọ́ sórí òkè Kamẹli, n óo wá wọn kàn níbẹ̀; n óo sì mú wọn. Bí wọ́n bá sá kúrò níwájú mi, tí wọ́n sápamọ́ sí ìsàlẹ̀ òkun, n óo pàṣẹ fún ejò níbẹ̀, yóo sì bù wọ́n jẹ.

4 Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lẹ́rú, tí wọn ń kó wọn lọ, n óo pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀tá pa wọ́n. N óo dójúlé wọn láti ṣe wọ́n ní ibi, n kò ní ṣe wọ́n ní rere.”

5 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,òun ló fọwọ́ kan ilẹ̀,tí ilẹ̀ sì yọ́,tí gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,tí gbogbo nǹkan ru sókè bí odò Naili,tí ó sì lọ sílẹ̀ bí odò Naili ti Ijipti;

6 OLUWA tí ó kọ́ ilé gíga rẹ̀ sí ojú ọ̀run,tí ó gbé awọsanma lé orí ilẹ̀ ayétí ó pe omi òkun jáde,tí ó sì dà á sórí ilẹ̀,OLUWA ni orúkọ rẹ̀.

7 Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti.

8 Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.

10 Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’

Dídá Israẹli Pada Sípò Lọ́jọ́ Iwájú

11 “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí.

12 Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13 “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tánkí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé.Ọgbà àjàrà yóo so,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tánkí àkókò ati gbin òmíràn tó dé.Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké.

14 N óo dá ire Israẹli, àwọn eniyan mi, pada,wọn yóo tún àwọn ìlú tí wọ́n ti wó kọ́,wọn yóo sì máa gbé inú wọn.Wọn yóo gbin àjàrà,wọn yóo sì mu ọtí waini rẹ̀.Wọn yóo ṣe ọgbà,wọn yóo sì jẹ èso rẹ̀.

15 N óo fẹsẹ̀ àwọn eniyan mi múlẹ̀lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn,a kò sì ní ṣí wọn nípò pada mọ́lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn.Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9