Amosi 6 BM

Ìparun Israẹli

1 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n wà ninu ìdẹ̀ra ní Sioni, ati àwọn tí wọn ń gbé orí òkè Samaria láìléwu, àwọn eniyan ńláńlá ní Israẹli, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé.

2 Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ?

3 Ẹ kò fẹ́ gbà pé ọjọ́ ibi ti súnmọ́ tòsí; ṣugbọn ẹ̀ ń ṣe nǹkan tí yóo mú kí ọjọ́ ẹ̀rù tètè dé.

4 Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn!

5 Àwọn tí ń fi hapu kọ orin ìrégbè, tí wọ́n sì ń ṣe ohun èlò orin fún ara wọn bíi Dafidi.

6 Àwọn tí wọn ń fi abọ́ mu ọtí, tí wọn ń fi òróró olówó iyebíye para, ṣugbọn tí wọn kò bìkítà fún ìparun Josẹfu.

7 Nítorí náà, àwọn ni wọn yóo kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn, gbogbo àsè ati ayẹyẹ àwọn tí wọn ń nà kalẹ̀ sórí ibùsùn yóo dópin.

8 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.”

9 Bí ó bá ku eniyan mẹ́wàá ninu ìdílé kan, gbogbo wọn yóo kú.

10 Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?”Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.”Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.”

11 Wò ó! OLUWA pàṣẹ pé, a óo wó àwọn ilé ńlá, ati àwọn ilé kéékèèké lulẹ̀ patapata.

12 Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò.

13 Ẹ fọ́nnu pé ẹ̀yin ni ẹ ṣẹgun ìlú Lodebari, ẹ̀ ń wí pé: “Ṣebí agbára wa ni a fi gba ìlú Kanaimu.”

14 OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9