1 OLUWA Ọlọrun fi ìran kan hàn mí! Ó ń kó ọ̀wọ́ eṣú jọ ní àkókò tí koríko ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ sí yọ sókè, lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ti ọba tán.
2 Nígbà tí àwọn eṣú náà ti jẹ gbogbo koríko ilẹ̀ náà tán, mo ní, “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́ dáríjì àwọn eniyan rẹ. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí pé wọ́n kéré níye?”
3 OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.”
4 OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí Ọlọrun pe iná láti fi jẹ àwọn eniyan rẹ̀ níyà. Iná náà jó ibú omi, ráúráú ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ilẹ̀ pàápàá.
5 Nígbà náà ni mo dáhùn pé: “OLUWA Ọlọrun, jọ̀wọ́, dáwọ́ dúró. Báwo ni àwọn ọmọ Jakọbu yóo ṣe là, nítorí wọ́n kéré níye?”
6 OLUWA bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, ó ní, “Ohun tí o rí kò ní ṣẹlẹ̀.”
7 OLUWA Ọlọrun tún fi ìran mìíràn hàn mí: mo rí i tí OLUWA mú okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé lọ́wọ́; ó dúró lẹ́bàá ògiri tí a ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé wọ̀n.
8 Ó bi mí pé: “Amosi, kí ni o rí?” Mo bá dáhùn pé, “Okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé.” Ó ní: “Wò ó! Mo ti fi okùn ìwọ̀n àwọn mọlémọlé sí ààrin àwọn ọmọ Israẹli, eniyan mi; n kò ní fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.
9 Gbogbo ibi gíga Isaaki yóo di ahoro, ilé mímọ́ Israẹli yóo parun, n óo yọ idà sí ìdílé ọba Jeroboamu.”
10 Nígbà náà ni Amasaya, alufaa Bẹtẹli, ranṣẹ sí Jeroboamu, ọba Israẹli pé: “Amosi ń dìtẹ̀ mọ́ ọ láàrin àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóo sì ba gbogbo ilẹ̀ yìí jẹ́.
11 Ó ń wí pé, ‘Jeroboamu yóo kú sójú ogun, gbogbo ilé Israẹli ni a óo sì kó lẹ́rú lọ.’ ”
12 Amasaya sọ fún Amosi pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ aríran, pada lọ sí ilẹ̀ Juda, máa lọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀, kí wọ́n sì máa fún ọ ní oúnjẹ.
13 Má sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Bẹtẹli mọ́, nítorí ibi mímọ́ ni, fún ọba ati fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
14 Amosi bá dáhùn, ó ní: “Èmi kì í ṣe wolii tabi ọmọ wolii, darandaran ni mí, èmi a sì tún máa tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́.
15 OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun.
16 Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA nisinsinyii, ṣé o ní kí n má sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli mọ́, kí n má sì waasu fún àwọn ọmọ Isaaki mọ́?
17 Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLUWA sọ: ‘Iyawo rẹ yóo di aṣẹ́wó láàrin ìlú, àwọn ọmọ rẹ lọkunrin ati lobinrin yóo kú sójú ogun, a óo pín ilẹ̀ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn; ìwọ pàápàá yóo sì kú sí ilẹ̀ àwọn alaigbagbọ; láìṣe àní àní, a óo kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ìgbèkùn.’ ”