1 OLUWA ní: “Àwọn ará Moabu ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n sọná sí egungun ọba Edomu, wọ́n sun ún, ó jóná ráúráú.
2 Nítorí náà, n óo sọ iná sí Moabu, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Kerioti ní àjórun. Ninu ariwo ogun ati ti fèrè ni Moabu yóo parun sí,
3 n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ run.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
4 Ó ní: “Àwọn ará Juda ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí wọ́n ti kọ òfin èmi OLUWA sílẹ̀, wọn kò sì rìn ní ìlànà mi. Àwọn oriṣa irọ́ tí àwọn baba wọn ń bọ, ti ṣì wọ́n lọ́nà.
5 Nítorí náà, n óo sọ iná sí Juda, yóo sì jó àwọn ibi ààbò Jerusalẹmu ní àjórun.”
6 OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji.
7 Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́.
8 Wọ́n sùn káàkiri yí pẹpẹ inú ilé Ọlọrun wọn ká, lórí aṣọ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn onígbèsè wọn; wọ́n ń mu ọtí tí àwọn kan fi san owó ìtanràn.
9 “Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò.
10 Èmi fúnra mi ni mo mu yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo mu yín la aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, kí ẹ lè gba ilẹ̀ àwọn ará Amori.
11 Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
12 Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́.
13 Wò ó, n óo tẹ̀ yín ní àtẹ̀rẹ́ ní ibùgbé yín, bí ìgbà tí ọkọ̀ kọjá lórí eniyan.
14 Ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ yóo mú àwọn tí wọ́n lè sáré; ipá àwọn alágbára yóo pin, akikanju kò sì ní lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀.
15 Tafàtafà kò ní lè dúró, ẹni tí ó lè sáré kò ní lè sá àsálà; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣin kò ní lè gba ara wọn kalẹ̀.
16 Ìhòòhò ni àwọn akọni láàrin àwọn ọmọ ogun yóo sálọ ní ọjọ́ náà.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.