Ọbadaya 1 BM

OLUWA Yóo Jẹ Edomu Níyà

1 Ìran tí Ọbadaya rí nìyí, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Edomu pé:A ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,ó sì ti rán iranṣẹ rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè pé:“Ẹ múra, ẹ jẹ́ kí á lọ bá Edomu jagun!”

2 Ó sọ fún Edomu pé, “Wò ó, n óo sọ ọ́ di yẹpẹrẹ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù;gbogbo ayé pátá ni yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀sín.

3 Ìgbéraga rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé inú pàlàpálá òkúta,tí ibùgbé rẹ wà lórí òkè gíga,tí o sì ń wí ninu ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni ó lè fà mí lulẹ̀?’

4 Bí o tilẹ̀ fò lọ sókè bí ẹyẹ idì,tí ó tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ààrin àwọn ìràwọ̀,láti òkè náà ni n óo ti fà ọ́ lulẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

5 “Bí àwọn olè bá wá bá ọ lóru,tí àwọn ọlọ́ṣà bá wá ká ọ mọ́lé lọ́gànjọ́,ṣé wọn kò ní hàn ọ́ léèmọ̀?Ṣebí ohun tí wọ́n bá fẹ́ ninu ẹrù rẹ ni wọn óo kó?Bí àwọn tí wọn ń kórè àjàrà bá wá sọ́dọ̀ rẹ,ṣebí wọn a máa fi díẹ̀ sílẹ̀?

6 Ogun ti kó Esau,gbogbo ìṣúra rẹ̀ ni wọ́n ti kó tán!

7 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ọ dá majẹmu ti tàn ọ́ jẹ,wọ́n sì ti lé ọ títí dé ààlà ilẹ̀ rẹ;àwọn tí ẹ jọ ń gbé ní alaafia tẹ́lẹ̀ ti di ọ̀tá rẹ;àwọn ọ̀rẹ́ tí o gbẹ́kẹ̀lé ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè ọ́,o kò sì mọ̀.

8 “Ní ọjọ́ náà, ni n óo pa àwọn ọlọ́gbọ́n run ní Edomu,òye wọn yóo sì di òfo ní òkè Esau.

9 Ìwọ ìlú Temani,ìbẹ̀rùbojo yóo dé bá àwọn akọni rẹ,gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní òkè Esau ni a óo sì fi idà pa.

Àwọn Ìdí Tí A Fi Jẹ Edomu Níyà

10 “Nítorí ìwà ìkà tí ẹ hù sí àwọn ọmọ Israẹli, arakunrin yín,ojú yóo tì yína óo sì pa yín run títí lae.

11 Ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá ń kó ọrọ̀ wọn lọ,tí àwọn àjèjì wọ inú ìlú wọn,tí àwọn ọ̀tá sì ń ṣẹ́ gègé lórí Jerusalẹmu,ẹ dúró, ẹ̀ ń wò wọ́n;ẹ sì dàbí ọ̀kan ninu wọn.

12 O kì bá tí fi arakunrin rẹ ṣẹ̀sínní ọjọ́ ìpọ́njú rẹ̀;o kì bá tí jẹ́ kí inú rẹ dùn,ní ọjọ́ ìparun àwọn eniyan Juda;o kì bá tí fọ́nnu ní ọjọ́ ìbànújẹ́ wọn.

13 O kì bá tí wọ ìlú àwọn eniyan miní ọjọ́ ìpọ́njú wọn;o kì bá tí fi wọ́n ṣẹ̀sínní ọjọ́ àjálù wọn;o kì bá tí kó wọn lẹ́rùní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

14 O kì bá tí dúró sí oríta,kí o máa mú àwọn tí wọn ń gbìyànjú láti sá àsálà;o kì bá tí fà wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

Ọlọrun Yóo Dá Àwọn Orílẹ̀-Èdè Lẹ́jọ́

15 “Ọjọ́ ìdájọ́ OLUWA fẹ́rẹ̀ dé sórí àwọn orílẹ̀-èdè;a óo san án fún ọ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Ohun tí o bá ṣe, yóo pada sí orí ara rẹ.

16 Ẹ̀yin eniyan mi, bí ẹ ti jìyà ní òkè mímọ́ mi,bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà yóo jìyà;wọn óo jìyà yóo tẹ́ wọn lọ́rùn,wọn yóo sì wà gẹ́gẹ́ bí ẹni pé wọn kò sí rí.

Ìṣẹ́gun Israẹli

17 “Ṣugbọn ní òkè Sionini àwọn tí wọ́n bá sá àsálà yóo máa gbé,yóo sì jẹ́ òkè mímọ́;àwọn ọmọ Jakọbu yóo gba ohun ìní wọn pada.

18 Ilé Jakọbu yóo dàbí iná,ilé Josẹfu yóo dàbí ọ̀wọ́ iná,ilé Esau yóo sì dàbí àgékù koríko.Wọn yóo jó ilé Esau;àwọn ìran Esau yóo jó àjórun láìku ẹnìkan;nítorí pé OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

19 Àwọn tí wọn ń gbé Nẹgẹbu yóo gba òkè Edomu,àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ Ṣefelayóo gba ilẹ̀ àwọn ará Filistia;wọn yóo gba gbogbo agbègbè Efuraimu ati ilẹ̀ Samaria,àwọn ará Bẹnjamini yóo sì gba ilẹ̀ Gileadi.

20 Àwọn ọmọ Israẹlití wọ́n wà ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Halawọ́n óo gba ilẹ̀ Fonike títí dé Sarefati;àwọn eniyan Jerusalẹmu tí wọ́n wà ní oko ẹrú ní ilẹ̀ Sefaradiyóo gba àwọn ìlú tí ó wà ní Nẹgẹbu.

21 Àwọn olùgbàlà yóo lọ láti Sioni,wọn yóo jọba lórí òkè Edomu;ìjọba náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.”

orí

1