23 Ẹ dákẹ́ ariwo orin yín; n kò fẹ́ gbọ́ ohùn orin hapu yín mọ́.
24 Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣàn bí omi, kí òdodo sì máa ṣàn bí odò tí kò lè gbẹ.
25 “Ẹ gbọ́, ilé Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ ati ọrẹ wá fún mi ní gbogbo ogoji ọdún tí ẹ fi wà ninu aṣálẹ̀?
26 Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń sin ère Sakuti, ọba yín, ati Kaiwani, oriṣa ìràwọ̀ yín, ati àwọn ère tí ẹ ṣe fún ara yín.
27 Nítorí náà, n óo ko yín lọ sí ìgbèkùn níwájú Damasku.” OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọrun àwọn Ọmọ Ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.