1 Mo rí OLUWA, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ó pàṣẹ pé, “Lu àwọn òpó tẹmpili títí tí gbogbo àtẹ́rígbà rẹ̀ yóo fi mì tìtì, tí yóo sì wó lé gbogbo àwọn eniyan lórí. N óo jẹ́ kí ogun pa àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù lára wọn, Kò ní sí ẹyọ ẹnìkan ninu wọn tí yóo lè sálọ, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹnìkan tí yóo sá àsálà.
2 Bí wọ́n tilẹ̀ gbẹ́ ilẹ̀ tí ó jìn bí isà òkú, ọwọ́ mi yóo tẹ̀ wọ́n níbẹ̀; bí wọ́n gòkè lọ sí ojú ọ̀run, n óo wọ́ wọn lulẹ̀ láti ibẹ̀.
3 Bí wọ́n bá sápamọ́ sórí òkè Kamẹli, n óo wá wọn kàn níbẹ̀; n óo sì mú wọn. Bí wọ́n bá sá kúrò níwájú mi, tí wọ́n sápamọ́ sí ìsàlẹ̀ òkun, n óo pàṣẹ fún ejò níbẹ̀, yóo sì bù wọ́n jẹ.
4 Bí àwọn ọ̀tá bá kó wọn lẹ́rú, tí wọn ń kó wọn lọ, n óo pàṣẹ pé kí àwọn ọ̀tá pa wọ́n. N óo dójúlé wọn láti ṣe wọ́n ní ibi, n kò ní ṣe wọ́n ní rere.”