5 OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun,òun ló fọwọ́ kan ilẹ̀,tí ilẹ̀ sì yọ́,tí gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,tí gbogbo nǹkan ru sókè bí odò Naili,tí ó sì lọ sílẹ̀ bí odò Naili ti Ijipti;
6 OLUWA tí ó kọ́ ilé gíga rẹ̀ sí ojú ọ̀run,tí ó gbé awọsanma lé orí ilẹ̀ ayétí ó pe omi òkun jáde,tí ó sì dà á sórí ilẹ̀,OLUWA ni orúkọ rẹ̀.
7 Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti.
8 Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9 “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.
10 Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’
11 “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí.