Amosi 9:7-13 BM

7 Ọlọrun ní, “Ṣebí bí ẹ ti jẹ́ sí mi ni àwọn ará Etiopia náà jẹ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Àbí kì í ṣe bí mo ti mú àwọn ará Filistia jáde láti ìlú Kafitori, tí mo mú àwọn Siria jáde láti ìlú Kiri, ni mo mú ẹ̀yin náà jáde láti Ijipti.

8 Wò ó! Èmi OLUWA Ọlọrun ti fojú sí orílẹ̀-èdè tí ń dẹ́ṣẹ̀ lára, n óo sì pa á run lórí ilẹ̀ ayé; ṣugbọn, n kò ní run gbogbo ìran Jakọbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9 “N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.

10 Gbogbo àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ láàrin àwọn eniyan mi ni ogun yóo pa, gbogbo àwọn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Ibi kankan kò ní bá wa!’

11 “Ní ọjọ́ náà, n óo gbé àgọ́ Dafidi tí ó ti wó ró. N óo tún odi rẹ̀ mọ, n óo tún un kọ́ yóo sì rí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí.

12 Àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun àwọn tí wọ́n kù ní Edomu, ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí à ń fi orúkọ mi pè. Èmi OLUWA, tí n óo ṣe bí mo ti wí, èmi ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

13 “Ọjọ́ ń bọ̀, tí ọkà yóo so jìnwìnnì,tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní lè kórè rẹ̀ tánkí àkókò gbígbin ọkà mìíràn tó dé.Ọgbà àjàrà yóo so,tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè fi ṣe waini tánkí àkókò ati gbin òmíràn tó dé.Ọtí waini dídùn yóo máa kán sílẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá,ọtí waini yóo sì máa ṣàn jáde lára àwọn òkè kéékèèké.