Àwọn Adájọ́ 15:13-19 BM

13 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá, àwa óo dì ọ́, a óo sì gbé ọ lé wọn lọ́wọ́ ni, a kò ní pa ọ́ rárá.” Wọ́n bá mú okùn titun meji, wọ́n fi dì í, wọ́n sì gbé e jáde láti inú ihò àpáta náà.

14 Nígbà tí ó dé Lehi, àwọn Filistia wá hó pàdé rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA bà lé Samsoni tagbára tagbára, okùn tí wọ́n fi dè é sì já bí ìgbà tí iná ràn mọ́ fọ́nrán òwú. Gbogbo ìdè tí wọ́n fi dè é já kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

15 Ó rí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa, ó mú un, ó sì fi pa ẹgbẹrun ninu àwọn ará Filistia.

16 Samsoni bá dáhùn pé,“Páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa wọ́n jọ bí òkítì,Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni mo fi pa ẹgbẹrun eniyan.”

17 Lẹ́yìn tí ó wí báyìí tán, ó ju egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sílẹ̀, wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Ramati Lehi.

18 Òùngbẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ ẹ́ gidigidi, ó sì gbadura sí OLUWA, ó ní, “Ìwọ ni o ran èmi iranṣẹ rẹ lọ́wọ́ láti ṣẹgun lónìí, ṣugbọn ṣé òùngbẹ ni yóo wá gbẹ mí pa, tí n óo fi bọ́ sí ọwọ́ àwọn aláìkọlà wọnyi?”

19 Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí.