4 Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.”
5 Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún.
6 Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?”
7 Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.”
8 Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”
9 Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn.
10 Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n.