Daniẹli 4:16-22 BM

16 kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje.

17 Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’

18 “Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.”

19 Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.”Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.

20 Igi tí o rí, tí ó dàgbà, tí ó lágbára, tí orí rẹ̀ sì kan ọ̀run dé ibi pé gbogbo eniyan lè rí i,

21 tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.

22 “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.