Daniẹli 4:21-27 BM

21 tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.

22 “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.

23 Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’

24 “Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni.

25 A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́.

26 Olùṣọ́ náà pàṣẹ pé kí á fi gbòǹgbò igi náà sílẹ̀ ninu ilẹ̀; ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, dájúdájú, o óo tún pada wá jọba, nígbà tí o bá gbà pé Ọlọrun ni ọba gbogbo ayé.

27 Nítorí náà, kabiyesi, gba ìmọ̀ràn tí n óo fún ọ yìí; jáwọ́ ninu ẹ̀ṣẹ̀, sì máa ṣe òdodo, jáwọ́ ninu ìwà ìkà, máa ṣàánú fún àwọn tí a ni lára, bóyá èyí lè mú kí àkókò alaafia rẹ gùn sí i.”