Ẹkún Jeremaya 1:13-19 BM

13 “Ó rán iná láti òkè ọ̀run wá;ó dá a sí egungun mi;ó dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;ó sì dá mi pada.Mo dàbí odi,mo sì fi ìgbà gbogbo dákú.

14 “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,ó sì sọ mí di aláìlágbára.OLUWA ti fi mí léàwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.

15 “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.

16 “Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún;tí omijé ń dà lójú mi;olùtùnú jìnnà sí mi,kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le.Àwọn ọmọ mi ti di aláìní,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.

17 “Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́,Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́,OLUWA ti pàṣẹ pé,kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀;Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.

18 “Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe,nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀;ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan,ẹ kíyèsí ìjìyà mi;wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin milọ sí ìgbèkùn.

19 “Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi,ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí;àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú,níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri,tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára