Ẹkún Jeremaya 1:14-20 BM

14 “Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà,ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn,ó sì sọ mí di aláìlágbára.OLUWA ti fi mí léàwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.

15 “OLUWA ti fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn akọni mi mọ́lẹ̀;ó pe ọpọlọpọ eniyan jọ sí mi,ó ní kí wọ́n pa àwọn ọdọmọkunrin mi;OLUWA ti tẹ àwọn ọmọ Juda ní àtẹ̀rẹ́,bí ẹni tẹ èso àjàrà fún ọtí waini.

16 “Nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi ni mo ṣe sọkún;tí omijé ń dà lójú mi;olùtùnú jìnnà sí mi,kò sí ẹni tí ó lè dá mi lọ́kàn le.Àwọn ọmọ mi ti di aláìní,nítorí pé àwọn ọ̀tá ti borí wa.

17 “Sioni na ọwọ́ rẹ̀ fún ìrànwọ́,Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó ràn án lọ́wọ́,OLUWA ti pàṣẹ pé,kí àwọn aládùúgbò Jakọbu di ọ̀tá rẹ̀;Jerusalẹmu sì ti di eléèérí láàrin wọn.

18 “Ohun tí ó tọ́ ni OLUWA ṣe,nítorí mo ti ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀;ṣugbọn, ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan,ẹ kíyèsí ìjìyà mi;wọ́n ti kó àwọn ọdọmọbinrin ati ọdọmọkunrin milọ sí ìgbèkùn.

19 “Mo ké pe àwọn alajọṣepọ mi,ṣugbọn títàn ni wọ́n tàn mí;àwọn alufaa ati àwọn àgbààgbà mi ṣègbé láàrin ìlú,níbi tí wọn ti ń wá oúnjẹ kiri,tí wọn óo jẹ, kí wọn lè lágbára

20 “Bojúwò mí, OLUWA,nítorí mo wà ninu ìpọ́njú,ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́,nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ.Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ;bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.