1 Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Pasia, kí àsọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Jeremaya lè ṣẹ, OLUWA fi sí Kirusi ọba lọ́kàn láti kéde yíká gbogbo ìjọba rẹ̀ ati láti ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé:
2 “Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda.
3 Kí Ọlọrun wà pẹlu àwọn tí wọ́n jẹ́ eniyan rẹ̀. Ẹ lọ sí Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda, kí ẹ tún ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli kọ́, nítorí òun ni Ọlọrun tí wọn ń sìn ní Jerusalẹmu.
4 Ní gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan rẹ̀ ń gbé, kí àwọn aládùúgbò wọn fi fadaka, wúrà, dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn ta wọ́n lọ́rẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọrun.”
5 Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́.
6 Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.
7 Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu.