Ẹsira 10 BM

Ètò láti fi Òpin sí Igbeyawo láàrin àwọn Juu ati àwọn tí Wọn kì í ṣe Juu

1 Bí Ẹsira ti ń gbadura, tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń sọkún, tí ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ilé Ọlọrun, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí dúró yí i ká, tọmọde, tàgbà, tọkunrin, tobinrin. Àwọn náà ń sọkún gan-an.

2 Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

3 Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí.

4 Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.”

5 Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra.

6 Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.

7 Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu.

8 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ àwọn olórí ati àwọn àgbààgbà, ẹnikẹ́ni tí kò bá farahàn títí ọjọ́ mẹta, yóo pàdánù àwọn ohun ìní rẹ̀, a óo sì yọ ọ́ kúrò láàrin àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.

9 Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kẹta yóo fi ṣú, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọn ń gbé agbègbè Bẹnjamini ati Juda ni wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsan-an ni gbogbo wọn péjọ, wọn jókòó sí ìta gbangba níwájú ilé Ọlọrun. Gbogbo wọn ń gbọ̀n nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè wọ́n fún ati nítorí òjò tí ń rọ̀.

10 Ẹsira, alufaa, bá dìde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ti ṣẹ̀ níti pé ẹ fẹ́ obinrin àjèjì, ẹ sì ti mú kí ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli pọ̀ sí i.

11 Nítorí náà ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín, kí ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan náà ati kúrò lọ́dọ̀ àwọn obinrin àjèjì.”

12 Gbogbo àwọn eniyan náà kígbe sókè, wọ́n dáhùn pé, “Òtítọ́ ni o sọ, bí o ti wí ni a gbọdọ̀ ṣe.

13 Ṣugbọn àwọn eniyan wọnyi pọ̀, ati pé àkókò òjò nìyí; a kò lè dúró ní gbangba báyìí. Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ohun tí a lè parí ní ọjọ́ kan tabi ọjọ́ meji, nítorí ohun tí a ṣe yìí, a ti ṣẹ̀ gan-an

14 Jẹ́ kí àwọn olórí wa dúró fún gbogbo àwùjọ yìí, kí wọ́n dá ọjọ́ tí àwọn tí wọ́n fẹ́ iyawo àjèjì ninu àwọn ìlú wa yóo wá, pẹlu àwọn àgbààgbà, ati àwọn adájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ibinu Ọlọrun lórí ọ̀rọ̀ yìí yóo fi kúrò lórí wa.”

15 Gbogbo wọn ni wọ́n faramọ́ ìmọ̀ràn yìí àfi Jonatani, ọmọ Asaheli ati Jahiseaya, ọmọ Tikifa. Àwọn ọmọ Lefi meji: Meṣulamu ati Ṣabetai náà faramọ́ àwọn tí wọ́n lòdì sí i.

16 Àwọn tí wọ́n pada ti oko ẹrú dé gba ìmọ̀ràn yìí. Nítorí náà, Ẹsira alufaa yan àwọn olórí ninu ìdílé wọn, wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ní ọjọ́ kinni oṣù kẹwaa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí.

17 Nígbà tí yóo fi di ọjọ́ kinni oṣù kinni, wọ́n ti parí ìwádìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì.

Àwọn tí Wọ́n Gbé Àwọn Obinrin Àjèjì Níyàwó

18 Orúkọ àwọn alufaa tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Jeṣua ọmọ Josadaki ati àwọn arakunrin rẹ̀: Maaseaya ati Elieseri, Jaribu, ati Gedalaya.

19 Wọ́n ṣe ìpinnu láti kọ àwọn aya wọn sílẹ̀, wọ́n sì fi àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

20 Ninu ìdílé Imeri: Hanani, ati Sebadaya.

21 Ninu ìdílé Harimu: Maaseaya, Elija, Ṣemaaya, Jehieli, ati Usaya.

22 Ninu ìdílé Paṣuri: Elioenai, Maaseaya, Iṣimaeli, Netaneli, Josabadi, ati Elasa.

23 Orúkọ àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n fẹ́ àwọn obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Josabadi, Ṣimei, Kelaya, (tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Kelita), Petahaya, Juda, ati Elieseri.

24 Ninu àwọn akọrin, Eliaṣibu nìkan ni ó fẹ́ obinrin àjèjì.Orúkọ àwọn aṣọ́nà tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ṣalumu, Telemu, ati Uri.

25 Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì nìwọ̀nyí:Ninu ìdílé Paroṣi: Ramaya, Isaya, ati Malikija; Mijamini, Eleasari, Haṣabaya ati Benaaya.

26 Ninu ìdílé Elamu: Matanaya, Sakaraya, ati Jehieli; Abidi, Jeremotu, ati Elija.

27 Ninu ìdílé Satu: Elioenai, Eliaṣibu, ati Matanaya, Jeremotu, Sabadi, ati Asisa.

28 Ninu ìdílé Bebai: Jehohanani, Hananaya, Sabai, ati Atilai.

29 Ninu ìdílé Bani: Meṣulamu, Maluki, ati Adaaya, Jaṣubu, Ṣeali, ati Jeremotu.

30 Ninu ìdílé Pahati Moabu: Adina, Kelali, ati Benaaya; Maaseaya, Matanaya, ati Besaleli; Binui, ati Manase.

31 Ninu ìdílé Harimu: Elieseri, Iṣija, ati Malikija; Ṣemaaya, ati Ṣimeoni.

32 Bẹnjamini, Maluki ati Ṣemaraya.

33 Ninu ìdílé Haṣumu: Matenai, Matata, ati Sabadi; Elifeleti, Jeremai, Manase, ati Ṣimei.

34 Ninu ìdílé Bani: Maadai, Amramu, ati Ueli;

35 Benaaya, Bedeaya, ati Keluhi;

36 Faniya, Meremoti, ati Eliaṣibu,

37 Matanaya, Matenai ati Jaasu.

38 Ninu ìdílé Binui: Ṣimei,

39 Ṣelemaya, Natani, ati Adaaya,

40 Makinadebai, Ṣaṣai ati Ṣarai,

41 Asareli, Ṣelemaya, ati Ṣemaraya,

42 Ṣalumu, Amaraya, ati Josẹfu.

43 Ninu ìdílé Nebo: Jeieli, Matitaya, Sabadi, Sebina, Jadai, Joẹli, ati Benaaya.

44 Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ obinrin àjèjì ni wọ́n kọ àwọn aya wọn sílẹ̀ tọmọtọmọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10