Ẹsira 7 BM

Ẹsira Dé sí Jerusalẹmu

1 Lẹ́yìn náà, ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ọkunrin kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹsira, ọmọ Seraaya, ọmọ Asaraya, ọmọ Hilikaya,

2 ọmọ Ṣalumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu,

3 ọmọ Amaraya, ọmọ Asaraya, ọmọ Meraiotu,

4 ọmọ Serahaya, ọmọ Usi, ọmọ Buki,

5 ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, olórí alufaa.

6 Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7 Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili,

8 wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu.

9 Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun.

10 Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Àkọsílẹ̀ tí Atasasesi Ọba fún Ẹsira

11 Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí,

12 “Láti ọ̀dọ̀ Atasasesi ọba, sí Ẹsira, alufaa, tí ó tún jẹ́ akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run.

13 “Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ;

14 nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ,

15 ati pé kí o kó ọrẹ wúrà ati fadaka lọ́wọ́, tí ọba ati àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọrun Israẹli, tí ibùgbé rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

16 O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu.

17 “Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu.

18 Fadaka ati wúrà tí ó bá ṣẹ́kù, ìwọ ati àwọn eniyan rẹ, ẹ lò ó bí ó ti yẹ lójú yín ati gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun yín.

19 Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun ni kí o kó lọ sí Jerusalẹmu, níwájú Ọlọrun.

20 Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba.

21 “Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un.

22 Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́.

23 Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀.

24 A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun.

25 “Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n.

26 Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.”

Ẹsira Yin Ọlọrun

27 Ẹsira bá dáhùn pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, Ọlọrun àwọn baba wa, tí ó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ọ̀ṣọ́ sí tẹmpili Ọlọrun ní Jerusalẹmu,

28 tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10