Ẹsira 4 BM

Àtakò Sí Títún Ilé Ọlọrun Kọ́

1 Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli,

2 wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.”

3 Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.”

4 Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà.

5 Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia.

Àtakò sí Títún Jerusalẹmu Kọ́

6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi, àwọn kan kọ ìwé wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn tí ń gbé Juda ati Jerusalẹmu.

7 Ní àkókò ìjọba Atasasesi, ọba Pasia, ni àwọn wọnyi dìde: Biṣilamu, Mitiredati, Tabeeli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù. Wọ́n kọ̀wé sí ọba Pasia ní èdè Aremia, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀.

8 Rehumu, olórí ogun, ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ni wọ́n kọ ìwé ẹ̀sùn sí ọba Atasasesi, nípa Jerusalẹmu ní orúkọ

9 àwọn mejeeji ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù pẹlu àwọn adájọ́, àwọn gomina ati àwọn ará Pasia, àwọn eniyan Ereki, àwọn ará Babiloni ati àwọn eniyan Susa, àwọn ará Elamu,

10 pẹlu àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Osinapari, alágbára ati ọlọ́lá, kó wá láti máa gbé àwọn ìlú Samaria ati àwọn agbègbè tí wọ́n wà ní òdìkejì odò.

11 Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí: “Sí ọba Atasasesi, àwa iranṣẹ rẹ tí a wà ní agbègbè òdìkejì odò kí ọba.

12 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀.

13 Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù.

14 A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba.

15 Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run.

16 A fẹ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọba létí pé bí àwọn eniyan wọnyi bá kọ́ ìlú yìí tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀, kò ní ku ilẹ̀ kankan mọ́ fún ọba ní agbègbè òdìkejì odò.”

17 Ọba désì ìwé náà pada sí Rehumu, olórí ogun ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ati sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí wọn ń gbé Samaria ati agbègbè òdìkejì odò yòókù. Ó ní, “Mo ki yín.

18 Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.

19 Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn.

20 Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan.

21 Nítorí náà, ẹ pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró títí wọn yóo fi gbọ́ àṣẹ mìíràn láti ọ̀dọ̀ mi.

22 Ẹ má ṣe fi iṣẹ́ náà jáfara, nítorí tí ẹ bá fi falẹ̀, ó lè pa ọba lára.”

23 Lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n ka ìwé ọba tán sí etígbọ̀ọ́ Rehumu ati Ṣimiṣai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, Rehumu ati Ṣimiṣai yára lọ sí Jerusalẹmu pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, wọn sì fi ipá dá iṣẹ́ náà dúró.

24 Báyìí ni iṣẹ́ kíkọ́ ilé Ọlọrun ṣe dúró ní Jerusalẹmu títí di ọdún keji ìjọba Dariusi, ọba Pasia.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10