Ẹsira 2 BM

Àwọn tí Wọ́n Pada ti Oko Ẹrú Dé

1 Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀.

2 Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana.Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí:

3 Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172)

4 Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372)

5 Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775)

6 Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812)

7 Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)

8 Àwọn ọmọ Satu jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé marundinlaadọta (945)

9 Àwọn ọmọ Sakai jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé ọgọta (760)

10 Àwọn ọmọ Bani jẹ́ ẹgbẹta ó lé mejilelogoji (642)

11 Àwọn ọmọ Bebai jẹ́ ẹgbaata ó lé mẹtalelogun (623)

12 Àwọn ọmọ Asigadi jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mejilelogun (1,222)

13 Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666)

14 Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056)

15 Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454)

16 Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un

17 Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323)

18 Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112)

19 Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)

20 Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un

21 Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123)

22 Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta

23 Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128)

24 Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji

25 Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743)

26 Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621)

27 Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122)

28 Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)

29 Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta

30 Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156)

31 Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)

32 Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320)

33 Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725)

34 Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345)

35 Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630)

36 Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973)

37 Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052)

38 Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247)

39 Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017)

40 Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin

41 Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128)

42 Iye àwọn ọmọ àwọn aṣọ́nà:àwọn ọmọ Ṣalumu ati àwọn ọmọ Ateri, àwọn ọmọ Talimoni ati àwọn ọmọ Akubu; àwọn ọmọ Hatita ati àwọn ọmọ Ṣobai jẹ́ mọkandínlogoje (139)

43 Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili nìwọ̀nyí:àwọn ọmọ Siha, àwọn ọmọ Hasufa ati àwọn ọmọ Tabaoti;

44 àwọn ọmọ Kerosi, àwọn ọmọ Siaha ati àwọn ọmọ Padoni;

45 àwọn ọmọ Lebana, àwọn ọmọ Hagaba ati àwọn ọmọ Akubu;

46 àwọn ọmọ Hagabu, àwọn ọmọ Ṣamlai ati àwọn ọmọ Hanani;

47 àwọn ọmọ Gideli, àwọn ọmọ Gahari ati àwọn ọmọ Reaaya;

48 àwọn ọmọ Resini, àwọn ọmọ Nekoda ati àwọn ọmọ Gasamu;

49 àwọn ọmọ Usa, àwọn ọmọ Pasea, ati àwọn ọmọ Besai;

50 àwọn ọmọ Asina, àwọn ọmọ Meuni, ati àwọn ọmọ Nefisimu;

51 àwọn ọmọ Bakibuki, àwọn ọmọ Akufa, àwọn ọmọ Hahuri,

52 àwọn ọmọ Basiluti, àwọn ọmọ Mehida, ati àwọn ọmọ Haṣa,

53 àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,

54 àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa.

55 Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí:àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda;

56 àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli;

57 àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami.

58 Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).

59 Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí:

60 Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).

61 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀).

62 Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.

63 Gomina sọ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ninu àwọn oúnjẹ mímọ́ jùlọ, títí tí wọn yóo fi rí alufaa kan tí ó lè lo Urimu ati Tumimu láti wádìí lọ́wọ́ OLUWA.

64 Àpapọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹgbaa, ó lé ọtalelọọdunrun (42,360).

65 Láìka àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin wọn tí wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin ó lé ojilelọọdunrun ó dín mẹta (7,337). Wọ́n sì tún ní igba (200) akọrin lọkunrin, ati lobinrin.

66 Àwọn ohun ọ̀sìn tí wọ́n kó bọ̀ nìwọ̀nyí: ẹṣin wọn jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹrindinlogoji (736) akọ mààlúù wọn jẹ́ igba ó lé marundinlaadọta (245)

67 Ràkúnmí wọn jẹ́ irinwo ó lé marundinlogoji (435), kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn jẹ́ ẹgbaata ó lé okoolelẹẹdẹgbẹrin (6,720).

68 Nígbà tí wọ́n dé ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, díẹ̀ ninu àwọn olórí ìdílé náà fi ọrẹ àtinúwá sílẹ̀ láti tún ilé Ọlọrun kọ́ sí ààyè rẹ̀.

69 Wọ́n ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára wọn ti tó. Wọ́n fi ọọdunrun ó lé mejila (312) kilogiramu wúrà ẹgbẹsan (1,800) kilogiramu fadaka ati ọgọrun-un (100) ẹ̀wù alufaa, ṣe ẹ̀bùn fún ilé OLUWA.

70 Àwọn alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn kan ninu àwọn eniyan náà ń gbé Jerusalẹmu ati agbègbè rẹ̀. Àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ń gbé àwọn ìlú tí ó wà nítòsí wọn, àwọn ọmọ Israẹli yòókù sì ń gbé àwọn ìlú wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10