5 Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́.
6 Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.
7 Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu.
8 Kirusi ọba fún Mitiredati, akápò ìjọba rẹ̀ ní àṣẹ láti kó wọn síta, ó sì kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Ṣeṣibasari, olórí ẹ̀yà Juda.
9 Iye àwọn nǹkan náà nìyí:Ẹgbẹrun kan (1,000) àwo wúrà,ẹgbẹrun kan (1,000) àwo fadaka,àwo turari mọkandinlọgbọn;
10 ọgbọ̀n àwokòtò wúrà,ẹgbaa ó lé irinwo ati mẹ́wàá (2,410) àwo fadaka kéékèèké,ẹgbẹrun (1,000) oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn.
11 Àpapọ̀ àwọn ohun èlò wúrà ati fadaka yìí jẹ́ ẹẹdẹgbaata ó lé irinwo (5,400). Ṣeṣibasari kó wọn lọ́wọ́ bí àwọn tí wọn kúrò ní oko ẹrú Babiloni ti ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.