Ẹsira 10:1-7 BM

1 Bí Ẹsira ti ń gbadura, tí ó ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ó ń sọkún, tí ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ilé Ọlọrun, àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí dúró yí i ká, tọmọde, tàgbà, tọkunrin, tobinrin. Àwọn náà ń sọkún gan-an.

2 Ṣekanaya, ọmọ Jehieli, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Elamu bá sọ fún Ẹsira pé: “A ti hùwà ọ̀dàlẹ̀ sí Ọlọrun wa, nítorí a ti lọ fẹ́ aya láàrin àwọn ẹ̀yà tí wọ́n yí wa ká, sibẹsibẹ, ìrètí ń bẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

3 Nítorí náà, jẹ́ kí á bá Ọlọrun wa dá majẹmu pé a óo lé àwọn obinrin àjèjì wọnyi lọ pẹlu àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwọ, oluwa mi, ati àwọn tí wọ́n bẹ̀rù òfin Ọlọrun wa wí, kí á ṣe é bí òfin ti wí.

4 Ọwọ́ rẹ ni ọ̀rọ̀ yí wà; dìde nílẹ̀ kí o ṣe é. A wà lẹ́yìn rẹ, nítorí náà ṣe ọkàn gírí.”

5 Ẹsira bá dìde nílẹ̀, ó wí fún gbogbo àwọn olórí alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n búra pé wọn yóo ṣe gẹ́gẹ́ bí Ṣekanaya ti sọ, wọ́n sì búra.

6 Nígbà náà ni Ẹsira kúrò níwájú ilé Ọlọrun, ó lọ sí yàrá Jehohanani, ọmọ Eliaṣibu, ibẹ̀ ni ó sùn ní alẹ́ ọjọ́ náà. Kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu nítorí pé ó ń banújẹ́ nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé.

7 Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu.