1 Àwọn ọmọ Juda wọnyi ni wọ́n pada dé láti oko ẹrú ní Babiloni, níbi tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, kó wọn lẹ́rú lọ. Wọ́n pada sí Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, olukuluku pada sí ìlú rẹ̀.
2 Àwọn olórí wọn ni: Serubabeli, Jeṣua, Nehemaya, Seraaya, Reelaya, Modekai, Biliṣani, Misipa, Bigifai, Rehumu ati Baana.Iye àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n pada láti oko ẹrú ní ìdílé ìdílé nìyí:
3 Àwọn ọmọ Paroṣi jẹ́ ẹgbaa lé mejilelaadọsan-an (2,172)
4 Àwọn ọmọ Ṣefataya jẹ́ ọọdunrun ó lé mejilelaadọrin (372)
5 Àwọn ọmọ Ara jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin lé marundinlọgọrin (775)
6 Àwọn ọmọ Pahati Moabu láti inú ìran Jeṣua ati Joabu jẹ́ ẹgbẹrinla lé mejila (2,812)
7 Àwọn ọmọ Elamu jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)