10 Nígbà tí àwọn mọlémọlé bẹ̀rẹ̀ sí fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀, àwọn alufaa gbé ẹ̀wù wọn wọ̀, wọ́n dúró pẹlu fèrè lọ́wọ́ wọn. Ìdílé Asafu, ẹ̀yà Lefi, ń lu kimbali wọn, wọ́n fí ń yin OLUWA, gẹ́gẹ́ bí ètò tí Dafidi, ọba Israẹli, ti ṣe.
11 Pẹlu orin ìyìn ati ìdúpẹ́ wọ́n ń kọrin sí OLUWA pẹlu ègbè rẹ̀ pé,“OLUWA ṣeun,ìfẹ́ rẹ̀ sí Israẹli dúró títí lae.”Gbogbo àwọn eniyan hó ìhó ìyìn sí OLUWA, nítorí pé wọ́n fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA lélẹ̀.
12 Ṣugbọn ọpọlọpọ àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi, ati àwọn olórí ìdílé, àwọn àgbàlagbà tí wọ́n gbọ́njú mọ ilé OLUWA ti tẹ́lẹ̀ sọkún, wọ́n kígbe sókè nígbà tí wọ́n rí bí a ti ń fi ìpìlẹ̀ ilé OLUWA náà lélẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mìíràn hó fún ayọ̀.
13 Kò sí ẹni tí ó lè mọ ìyàtọ̀ láàrin ariwo ẹkún ati ti ayọ̀ nítorí pé, gbogbo wọn ń kígbe sókè, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan sì gbọ́ igbe wọn ní ọ̀nà jíjìn réré.