14 A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba.
15 Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run.
16 A fẹ́ tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọba létí pé bí àwọn eniyan wọnyi bá kọ́ ìlú yìí tí wọ́n sì mọ odi rẹ̀, kò ní ku ilẹ̀ kankan mọ́ fún ọba ní agbègbè òdìkejì odò.”
17 Ọba désì ìwé náà pada sí Rehumu, olórí ogun ati Ṣimiṣai, akọ̀wé, ati sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tí wọn ń gbé Samaria ati agbègbè òdìkejì odò yòókù. Ó ní, “Mo ki yín.
18 Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.
19 Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn.
20 Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan.