9 àwọn mejeeji ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù pẹlu àwọn adájọ́, àwọn gomina ati àwọn ará Pasia, àwọn eniyan Ereki, àwọn ará Babiloni ati àwọn eniyan Susa, àwọn ará Elamu,
10 pẹlu àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Osinapari, alágbára ati ọlọ́lá, kó wá láti máa gbé àwọn ìlú Samaria ati àwọn agbègbè tí wọ́n wà ní òdìkejì odò.
11 Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé náà nìyí: “Sí ọba Atasasesi, àwa iranṣẹ rẹ tí a wà ní agbègbè òdìkejì odò kí ọba.
12 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Juu tí wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa ti lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí tún ìlú burúkú náà, tí ó kún fún ọ̀tẹ̀ kọ́. Wọ́n ti mọ odi rẹ̀, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ parí ìpìlẹ̀ rẹ̀.
13 Kabiyesi, tí wọ́n bá fi lè kọ́ ìlú náà parí, tí wọ́n sì parí odi rẹ̀, wọn kò ní san owó ìṣákọ́lẹ̀ mọ́. Eléyìí yóo sì dín owó tí ń wọ àpò ọba kù.
14 A kò lè rí ohun tí kò dára kí á má sọ nítorí pé abẹ́ rẹ ni a ti ń jẹ; nítorí náà ni a fi gbọdọ̀ sọ fún ọba.
15 Ìmọ̀ràn wa ni pé, kí ọba pàṣẹ láti lọ wá àkọsílẹ̀ tí àwọn baba ńlá yín ti kọ. Ẹ óo rí i pé ìlú ọlọ̀tẹ̀ ni ìlú yìí. Láti ìgbà laelae ni wọ́n ti jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba agbègbè wọn. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi pa ìlú náà run.