1 Wolii Hagai ati wolii Sakaraya, ọmọ Ido, bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Juu tí wọ́n wà ni Juda ati Jerusalẹmu ní orúkọ Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó jẹ́ orí fún wọn.
2 Nígbà tí Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Jeṣua, ọmọ Josadaki gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lórí àtikọ́ ilé Ọlọrun ní Jerusalẹmu, àwọn wolii Ọlọrun mejeeji sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
3 Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ?
4 Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?”