Ẹsira 5:11-17 BM

11 “Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn.

12 Ṣugbọn nítorí pé àwọn baba wa mú Ọlọrun ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ní ilẹ̀ Kalidea lọ́wọ́, òun ni ó wó tẹmpili yìí palẹ̀, tí ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Babilonia.

13 Ṣugbọn ní ọdún kinni ìjọba Kirusi, ọba Babiloni, ó fi àṣẹ sí i pé kí wọ́n lọ tún tẹmpili náà kọ́.

14 Ó dá àwọn ohun èlò wúrà ati ti fadaka pada, tí Nebukadinesari kó ninu ilé OLUWA ní Jerusalẹmu, lọ sí ilé oriṣa rẹ̀ ní Babiloni tẹ́lẹ̀. Gbogbo nǹkan wọnyi ni Kirusi ọba kó jáde kúrò ninu tẹmpili ní Babiloni, ó kó wọn lé Ṣeṣibasari lọ́wọ́, ẹni tí ó yàn ní gomina lórí Juda.

15 Ó sọ fún un nígbà náà pé, “Gba àwọn ohun èèlò wọnyi, kó wọn lọ sinu tẹmpili tí ó wà ní Jerusalẹmu, kí ẹ sì tún tẹmpili náà kọ́ sí ojú ibi tí ó wà tẹ́lẹ̀.”

16 Ṣeṣibasari bá wá, ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní Jerusalẹmu. Láti ìgbà náà ni iṣẹ́ ti ń lọ níbẹ̀ títí di ìsinsìnyìí, kò sì tíì parí.’

17 “Nítorí náà, kabiyesi, tí ó bá dára lójú rẹ, jẹ́ kí wọ́n lọ wo ìwé àkọsílẹ̀ ní Babiloni bí kìí bá ṣe nítòótọ́ ni Kirusi pàṣẹ pé kí wọ́n tún ilé Ọlọrun kọ́ ní Jerusalẹmu. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí á mọ ohun tí o fẹ́ kí á ṣe nípa ọ̀rọ̀ yìí.”