3 Ní àkókò kan náà, Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò ati Ṣetari Bosenai ati gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá sí ọ̀dọ̀ wọn, wọ́n bi wọ́n léèrè pé: “Ta ló fun yín láṣẹ láti kọ́ tẹmpili yìí ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ?
4 Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?”
5 Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà.
6 Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí:
7 “Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́.
8 “A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú.
9 “A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ.